Ọba Olaoye lanfaani lati ri awọn akẹẹkọ at'awọn olukọ naa lasiko ti o kan sí ẹka ileeṣẹ ọmogun Naijiria to wa niluu Ibadan nibi ti kabiyesi ti gboṣuba kare fun ọga agba oludari ẹka naa to wa ni agbegbe Ojoo fun iṣẹ takun takun ti wọn ṣe lori bi wọn ṣe doola awọn akẹẹkọ at'awọn olukọ naa.
Chatta ninu fidio kan to fi sori ikanni Instagram rẹ, sọ pe oun sọrọ sita lori iṣẹlẹ naa lẹyin ti awọn eeyan n fi oun ṣe yẹyẹ lori ọrọ naa lori ayelujara.
Ẹsun mejila ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu iwa ajẹbanu ni ajọ naa fi kan Miyetti Allah niwaju ile-ẹjọ, eyi ti wọn sọ pe wọn tẹwọ gba obitibiti owo ilẹ okeere ọhun, ti wọn lo lodi si ofin.
Gomina tẹlẹri nipinlẹ Anambra sọ pe ọpọ awọn ẹtọ oun ni ijọba ilẹ Naijiria fi n dunkooko mọ oun, ati pe gbogbo awọn to duro gẹgẹ bi alatako ijọba ni wọn n dojukọ idunkooko loriṣiriṣi.
Adele Alukoro fun ẹka ologun apapọ lapa Ariwa-Ila-Oorun Naijiria, Ọgagun Muhammed Goni, fidi ikọlu naa mulẹ ninu atẹjade to fi sita l'Ọjọbọ, ọjọ kẹsan-an oṣu Keje ọdun 2026 yii.
CBN sọ pe ki gbogbo awọn to n kọ lati maa gba owo ọgọrun kan naira naa dẹkun iwa naa bayii, nitori pe owo ọhun ṣi n jẹ itẹwọgba labẹ aṣẹ, akoso ati ofin ilẹ Naijiria.
Ẹgbẹ naa ti orukọ wọn n jẹ Traditional Religion Worshippers Association of Osun State (TRAWSO), ṣekilọ yii lasiko ti wọn n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Oṣogbo lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii.
James ninu fidio kan ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Delta, Bright Edafe fi sita lọjọ Aiku, ṣalaye pe oun mọ-ọn-mọ wọgbo lọ, oun si pe iya oun lori aago pe wọn ti ji oun gbe.
Aṣoju ajọ IMF ni Naijiria, Christian Ebeke, sọ niluu Eko pe nnkan bii ida meji owo ti ijọba Naijiria na ni ko si akọsilẹ rẹ rara, bo tilẹ jẹ pe o yẹ ki akọsilẹ rẹ wa.
Davido sọ fun BBC News Africa wi pe ko ṣee ṣe ki oun kọ eti ikun si eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria papaa julọ ijinigbe awọn akẹkọọ mọkandinlogoji atawọn olukọ meje to ṣẹlẹ ni ijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Oyo.
Atẹjade ti ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ati Osun fisita lori ayajọ ẹgbẹ okunkun 7-7, ti wa n sin awọn araalu ni gbẹrẹ ipakọ pe ki wọn fura nipa ọsẹ tawọn ẹlẹgbẹ okunkun naa le se.okunkun naa le se.
Ẹ o ranti pe bii ọsẹ mẹta sẹyin ni ileeṣẹ ọlọpaa kede pe afurasi adigunjale ni Surii Ilupeju ati pe ọpọ awọn ohun ija oloro bii ibọn atawọn nnkan mii ni awọn ba ninu ile rẹ nigba ti awọn ṣabẹwo sibẹ.
Lọjọ kẹẹdọgbọn oṣù Karun un lawọn janduku agbébọn yawọ ile ẹkọ girama to wa ni Esinele ati ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni Yawota ní ìjọba ìbílẹ̀ Oriire; nibi ti wọn ti ji àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ to le logoji lọ.
Atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ to n ri si eto irinna silẹ okeere, Imomotimi Ebienfa fi lede lọjọ Karun-un, oṣu Keje sọ pe awọn eeyan to padanu ẹmi wọn naa ni Emeka Charles Ibegbeu ati Nnaemeka Mathew Andrew Ekepynong.
We have put an assorted mix of pics here for your enjoyment. We are always hungry for more - so if you have taken or have
access to some pics remotely related to our issue, please do not hesitate to send them to the web admin team