Our Services



News From The BBC

A Yoruba Perspective


Ọ̀rọ̀ Soun Ogbomoso àtí Ìmáàmù Àgbà tún ṣẹ́yọ, Iléẹjọ́ so Ìmáàmù lọ́wọ́kọ́ lórí ìfinijoyè, Soun ní ìkọjá-àyè ni
Lọsẹ to kọja ni Sheikh Ayilara fi oye Asiwaju/Baba Isale Adini ilẹ Ogbomoso da Sẹnẹtọ Adeseun to ṣoju ẹkun aarin gbungbun Oyo laarin ọdun 2011 si 2015 nile aṣofin agba l'Abuja lọla.

Wo bí ayẹyẹ ìgbadé Owa Obokun tuntun, Adesuyi Haastrup, yóò ṣe wáyé n'Ilesa
Ọba Adesuyi to ti figba kan ri jẹ igbakeji gomina ipinlẹ Osun ni yoo jẹ Owa kọkandinlaadọta (49th) ilẹ Ijesa.

'Bí àwọn èèyàn bá rí mi, ọmọ gómìnà Adeleke ni wọ́n ń pè mí nítorí pé a jọra gidigidi'
Ọgbẹni Oluwaseyi Afonriwo jẹ ẹni ti ọpọ ti tọka si pe o jọ gomina Adeleke bi imumu.

Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Ṣé lóòótọ́ ni Portable yóò ṣe ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́ta gẹ́gẹ́bí iléẹjọ́ ṣe pàṣẹ́?
Ọdun 2023 ni Portable ti wa lẹnu ẹjọ naa to da lori lilu eeyan kan ati jiji ohun elo orin.

Àwọn òṣìṣẹ́ bínú sí ìjọba Naijiria láyàájọ́ ọjọ́ òṣìṣẹ́
Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ, (NLC) lorilẹede yii; Kọmureedi Joe Ajaero ati Festus Osifo(TUC), koro oju si ijọba Naijiria, pẹlu alaye pe ko yẹ ki oṣiṣẹ tun di atọrọjẹ lẹyin iṣẹ ti wọn n ṣe.

Ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí ISWAP jẹ́wọ́ pé àwọn ló pa èèyàn 26 ní Borno, kí lèyí túmọ̀ sí fún àbò Nàìjíríà?
Loju opo ayelujara Telegram wọn ni ISWAP ti jẹwọ pe ikọlu to pa awọn eeyan naa ko ṣẹyin awọn.

Wo bí o ṣe lè mọ iléeṣẹ́ tó fi orúkọ sílẹ̀ pẹ̀lu CAC
Ninu atẹjade CAC ni wọn ti kilọ pe pe ẹni to ba kuna lati forukọ ileeṣẹ rẹ silẹ yoo fi ẹwọn jura.

Wọn ti ko ọmọ Naijiria 203 tó há sí Libya padà wálé
Ajọ International Organization for Migration (IOM) pẹlu ajọṣepọ ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, 'National Emergency Management Agency' (NEMA), ni wọn ko wọn wale pẹlu awọn alẹnulọrọ mi-in.

Owu Waterfalls, ibùdó afẹ́ 'tó léwu ní lílọ̀ láì mú ẹ̀ṣọ́ aláàbò dáni'
Omi atapata da silẹ, Owu Waterfalls yii wa lara awọn omi atapata da walẹ to ga julọ lorilẹ Afirika to si rẹwa pupọ fun oju.

Nńkan ò ṣe mi o, mo wà láàyè -King Sunny Ade
Loju opo Instagram rẹ ni KSA ṣalaye ọrọ si lọjọ keji iroyin to kọkọ jade nipa alaafia rẹ, ati pe wọn ko ri i.

Darapọ̀ mọ́ wa lórí WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ

Kí ni òfin sọ nípa títàbùkù owó ilẹ̀ òkèèrè tó mú E-Money wọ gbaga EFCC?
Ẹ̀sùn pé ó ṣe owó ilẹ̀ òkèèrè lọ́nà àìtọ́ ni gbajúmọ̀ náà ń kojú, bí wọ́n ṣe fẹ̀sùn kàn-án pé ó ná owó dọ́là ilẹ̀ Amẹ́ríkà lọ́nà àìtọ́ èyí tí wọ́n ní ó lòdì sí òfin Foreign Exchange Act.

Àtúntò tó gba iṣẹ́ lọ́wọ́ àwọn alákóòṣo àti òṣìṣẹ́ 200 ní iléeṣẹ̀ ìfọporọ̀bì Naijiria, NNPCL, ohun tí a mọ̀ rèé
NNPCL jawe gbele ẹ bakan naa fawọn ọga agba mii nile iṣẹ ifọporọbi ọhun, lara wọn ni Ọgbẹni Bala Wunti to jẹ adari ẹka to n ri si okowo labẹ NNPCL.

Àwọn Boko Haram tí fídíò ṣàfihàn pé wọ́n balẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Oyo, ohun tí a mọ̀ rèé
Oju ọna marosẹ Ibadan ni wọn ni awọn Boko Haram ọhun ti n sọkalẹ sipinlẹ Oyo, ki wọn too da wọn duro.

Kí nídìí tí ìjọba àpapọ̀ fi fẹ́ wọ́gilé ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ sílẹ̀ òkèèrè fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ ètò BEA?
Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́ Nàìjíríà, Tunji Alausa ló kéde ìpinnu ìjọba náà lásìkò tó gbàlejò ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ Nàìjíríà lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

Ó ti pé ọgọ́rùn-ún ọjọ́ tí Amẹrika dá owó ìrànwọ́ USAID sílẹ̀ òkèèrè dúró - àwọn wo ló pàdánù jùlọ?
Owo to to $63bn ni Amẹrika na lọdun 2024 gẹgẹ bii owo iranwọ silẹ okeere.

Iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ Mínísítà lẹ́yìn ẹ̀sùn ìfipá bá ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún lò pọ̀
Hengari, ẹni ọdun mọkandinlọgọta (59), loun ko jẹbi ẹsun naa nigba to foju han ni kootu lọjọ Aje.

Òṣìṣẹ́ Access Bank tó ya fídíò ìhòhò obìnrin 400 níbi iṣẹ yóò fojú ba ilé-ẹjọ́
Opin ọsẹ ni iroyin jade, pe oṣiṣẹ banki naa ya fidio ihoho awọn oṣiṣẹ obinrin ni banki ọhun, ti iye wọn to irinwo.

Ṣé lóòtọ́ ni Gómìnà Adeleke ń gbèrò láti bẹ́ kìjà kúrò ní PDP lọ sí APC?
Ẹgbẹ Oṣelu APC ni Gomina Adeleke pẹlu ti kuro wa si ẹgbẹ oṣelu PDP lẹyin iku ẹgbọn rẹ, Isiaka Adeleke to jẹSẹnetọ lẹgbẹ oṣelu naa nigba naa lọhun.

Ṣé lóòótọ́ ni pé Naijiria ti di orílẹ̀èdè ẹlẹ́gbẹ́ òṣèlú kan?
Oloṣelu ki i deede fi ẹgbẹ to gbe wọn depo silẹ bẹẹ ki wọn lọọ maa darapọ mọ ẹgbẹ alatako, ṣugbọn ohun to n ṣẹlẹ lọwọ ni Naijiria ree.

Lẹ́yìn ìsìnkú Póòpù Francis, Ìjọ Kátólíìkì kéde ọjọ́ tí wọn yóò yàn póòpù tuntun
Ọsan ọjọ akọkọ tiwọn ba wọ inu ipade idakọnkọ naa ni wọn yoo di ipele akọkọ idibo naa. Amọ, yoo to igba mẹrin ọtọọtọ ti wọn yoo maa dibo lojoojumọ lẹyin eyi.

NDIC bẹ̀rẹ̀ sísan owó fún àwọn tó fowópamọ́ sí Heritage Bank to kógbáwọlé
Ni oṣu kẹfa ọdun 2024 ni Banki Heritage ti kogba wọle ti ọpọ awọn to fi owo pamọ sibẹ si ti n poungbe fun sisan owo wọn pada.

Àjọ NAPTIP dóòlà ọmọ Naijiria mẹ́sàn-an tí wọ́n fẹ́ẹ́ tàn ṣòwò ẹrú lọ si Libya
Aliyu Abubakar, adari ajọ naa fun ipinlẹ Zamfara, ṣalaye pe ẹnu ibode Babura, nipinlẹ Jigawa ni awọn ti doola awọn eeyan mẹsan-an naa.

Mi ò kábàmọ́ọ̀ pé ìyàwó mi tó kú nigbà tó fẹ́ bímọ kò forúkọ sílẹ̀ nílé ìwòsàn - Folajimi
Ọgbẹni Akinbobola Folajimi sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu BBC pe kii ṣe ile iwosan loun bi awọn ọmọ oun meji toun ti bi ṣaaju si.

FBI mú èèyàn 22 ní Naijiria fún ẹ̀sùn fífi àwòràn ìhòhò lu jìbìtì lórí ayélujára
Ajọ EFCC ilẹ Naijiria ati FBI ni iroyin sọ pe wọn jọ ṣiṣẹ pọ lati fi oju awọn ọmọ Naijiria to n lu jibiti naa han.

Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn tó ń fi èèyàn ṣòwò ẹrú ní Ibadan, dóòlà èèyàn 84
A gbọ pe pupọ ninu awọn ẹni ti ọlọpaa doola naa lo jẹ ọmọ orilẹede Democratic Republic of Congo ti wọn tan wa si Naijiria pẹlu ẹtan pe wọn yoo fun wọn ni iṣẹ.

Boko Haram fi àdò olóró gbẹ̀mí èèyàn 26, yìnbọn pa méje míràn ní Borno
Lasiko ti awọn eeyan ilu naa n ṣe ọfọ eeyan kan ti wọn ṣẹṣẹ sin oku rẹ tan lawọn agbebọn naa ṣina ibọn bo awọn eeyan ti wọn si pa awọn meje ti wọn pa ni Koful.

Ta a ni Aisha Achimugu, oníṣòwò ńlá tí EFCC mú fún ẹ̀sùn jìbìtì ?
Ṣaaju ni EFCC ti kede pe awọn n wa Achimugu lori ẹsun jibiti, fifi iṣẹ ire boju lati kowo jọ (Money laundering).

Ta làwọn ọmọ ilẹ̀ Africa mẹ́ta tó ti jẹ Póòpù ìjọ Àgùdà, kí lò dé tí aláwọ̀ dúdú kankan kò dépo náà mọ́ lẹ́yìn wọn?
Gẹgẹ bawọn onpitan ṣe wi, poopu mẹta lo ti jẹ ri ti wọn ti orirun wọn jẹ ti Africa, eyi to sunmọ ju ninu wọn ni wọn ni iku rẹ ti le ni ẹgbẹrun kan ati ẹẹdẹgbẹta (1,500 years ago.)

Ẹni tí wọn ò bá bú tó ń bú èèyàn ni Peter Obi- Sanwo-Olu
Ninu atẹjade kan ti Gomina Sanwo-Olu fi sita lọjọ Aiku lo ti ni Peter Obi ko yẹ lẹni to yẹ ko maa sọrọ abuku si aarẹ to n ṣelu lọwọ, ati awọn olori to ti kọja.

Wo ojú, orúkọ àti àwòrán àwọn afurasí ọmọ Naijiria tó ṣe agbódegbà fún CBEX
Adajọ Emeka Nwite lo gbe idajọ yii kalẹ ni Ọjọbọ, ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹrin ọdun 2025 lẹyin ti ajọ EFCC gbe ẹjọ naa wa si ile ẹjọ.

HUMILITASCharleans' Contribution Worldwide

300

Charlean Doctors

250

Charlean Engineers

150

Charlean Lawyers

109

Charlean Professors

We always perform at our best when we work together

Our mission is to provide the means & technical know-how to accomplish the aforementioned with HUMILITAS - always