International News - A Yoruba Perspective

From BBC


Ilorin Rainstorm: Àwọn olùgbé rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjoba lẹ́yìn tí ìjì òjò tó rọ̀ nílùú Ilorin ba ńkan púpọ̀ jẹ́
Opo ina pupọ to fi mọ orule ile awọn eeyan ni ojo yii bajẹ ti ọpọ si ti di alainile lori bayi.

Ìsẹ̀lẹ̀ jákèjádò orílẹ̀èdè àgbáyé láàárín ìṣẹ́jú kan
Àkójọpọ̀ ìsẹ̀lẹ̀ jákèjádò àgbáyé láàárín ìṣẹ́jú kan lórí BBC.

Edo Election 2020: Godwin Obaseki wọlé ìbò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì ní ìpínlẹ̀ Edo
Ṣaaju ni Obaseki fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lọ si ẹgbẹ PDP lẹyin ti o fidi rẹmi ninu idibo abẹle fun ipo gomina ẹgbẹ oṣelu APC.

BBNaija 2020: Tani ẹ rò pé yóò lọ nílé ẹlẹ́gbọ̀n ọ́n àgbà BigBrotherNaijia lálẹ́ òní?
Àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì yìí ló yàn Laycon àti Trikyhtee bákan náà wọn mú Dorathy àti Ozo.

Coronavirus pandemic update: Wo àwọn orílẹ́-èdè tí kò ní coronavirus lágbàáyé
Ajakalẹ arun Coronavirus to n gba ẹbọ lọwọ gbogbo agbaye tan kalẹ pupọ ṣugbọn àwọn orilẹ-ede kan ko nii.

Coronavirus: Àlàyé rèé lórí ìdí tí wọn fi dá ìdánwò àbẹ́rẹ́ àjẹsára Oxford University dúró
AstraZeneca sàkàwé pé dídáwọ́ ìdánwó àbẹrẹ́ àjẹsára dúró díẹ̀ yìí jẹ ǹkan tó máa ń sábà wáyé.

Coronavirus in Africa: Wo àwọn ẹ̀rọ mẹ́wàá tí àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ ṣe nítorí arùn Covid-19
Arun Covid-19 ti kọlu miliọnu kan eeyan le diẹ nilẹ Afrika, ọpọ awọn onimọ ẹro bẹrẹ si n ṣe awọn ẹrọ igbalode láti gbogun tii.

Aṣẹyin ti Iṣẹyin, Oba Abd-Ganiyu Adekunle Salaueen Oloogunebi Ajinese 1 ti kéde pẹ orò ló kù láti lé àwọn ajínigbé
Aseyin ti Iseyin, Oba Abd-Ganiyu Adekunle Salaueen Oloogunebi Ajinese 1 sọ eyi lati kede ọdun ọrọ to n lọ lọwọ ni Iṣẹyin ni ipinlẹ Oyo.

Edo Election 2020: Wike kìlọ̀ pé àjọ INEC ò gbọdọ̀ kéde pé ètò ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Edo kò yanjú
Atẹjade lati ọdọ ẹgbẹ oṣelu PDP sọ pe awọn ọlọpaa n dunkoko mọ awọn Gomina ẹgbẹ awọn to wa ni Edo

Ritual killer: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọkùnrin tó gé akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ wẹ́lẹ́ wẹ́lẹ́ fún òògùn owó ní Ikorodu
Toluwalase Kembi ṣabẹwo si ọrẹkunrin rẹ ni Ikorodu eyi to sọ pe miliọnu meji loun gba lati fi ọmọdebinrin naa joogun.

Abiola Ebila: ''Operation Burst'' ti mú arákùnrin Eji olórí ''One Million Boys'' tó gba ipò Ebila
Lati igba ti Abiola Ebila ti fi iku ṣe ifa jẹ ni ''Eji'' ti gba ipo olori ninu ẹgbẹ okunkun ''One Million Boys.''

Bauchi Police: Ẹ wá wó arákùnrin tó pa ọmọ-ọmọ rẹ̀ tuntun jòjòló nítorí nípa ibálòpọ̀ ni wọ́n fi lóyún rẹ̀!
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Bauchi sọ wi pe ẹni ọdun aadọta ni arakunrin to pa ọmọ-ọmọ rẹ ni agbegbe Toro ni ipinlẹ Bauchi.

US Supreme Court: Donald Trump ní obìnrin bíi Ruth Bader ni yóò gba ipò rẹ́ ní iléẹjọ́ tó gajùlọ nílẹ̀ Amerika
Aisan jẹjẹrẹ lo mu ẹmi adajọ agba Ruth Bader Ginsburg lọ lẹni ọdun mẹtadinlaadọrun.

Coronavirus Update in Nigeria: Ìsìn àárín ọ̀sẹ̀ àti àdúrà ojoojúmọ́ lè bẹ̀rẹ̀ l'áwọn ilé ìjọsìn ní ìpínlẹ̀ Eko
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ni àlàkalẹ̀ oríṣiríṣi ló ti wà fún àwọn ìpele ẹ̀kọ́ ní ìpińlẹ̀ yìí pàápàá jùlọ èyí to ní i ṣe pẹ́lú pípéjọ sí ọgba ilé iwé.

Adult Bedwetting: Kí ló ń fa kí àgbàlagbà má a tọ̀ sí ilé?
Alaye re e lori ohun to n fa ki agbalagba ma a to si ara nigba gbogbo.

Coronavirus Update in Nigeria: Èèyàn 189 ní àrùn Coronavirus tún ṣẹ̀ṣẹ̀ ràn ní Nàìjíríà
Àpapọ̀ gbogbo ènìyàn to ti ni ààrùn Coronavirus ni Nàìjíríà báyìí gẹ́gẹ́ bi àkọsílẹ̀ àjọ NCDC ṣe fihàn ti pé 57,145

Abass Akande: Obesere lóun ló kàn lẹ́yìn olóògbé Barrister àti Kollington nínú iṣẹ́ orin Fuji
''Ko tiẹ dabi ẹni pe Barrister tiẹ ku rara, nitori gbogbo igba laye si n gbọ orukọ rẹ,'' Obesere lo woye bẹẹ.

Nollywood Yoruba: Kìí ṣe sinimá ni mò ń ṣe, ìṣẹ̀lẹ̀ ojú ayé gangan ní sùgbọ́n...
Ní kété ti eyí balẹ̀ ló tún ju fọ́nran ibi ti òun pẹ̀lú ìyàwó ọlẹ̀lẹ̀ ti ń fẹsẹ rajo.

Lagos School Building Collapse: Iléèwé míràn tún dàwó ní ìpínlẹ̀ Eko
Ajọ oṣiṣẹ pajawiri nipinlẹ Eko ni awọn ti de ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ni agbegbe Ile Epo Bus Stop, Iyana Ejigbo, ni ipinle Eko.

Palm Oil production: Wo ìdílé tí ìyá àti gbogbo ọmọ kara bọ iṣẹ́ ṣíṣe epo tà
Bi oun ati awọn ọmọ rẹ ṣe n pawọpọ ṣe iṣẹ epo pupa yii jẹ iwuri gidi gan.

LASEMA Lagos: Ọkọ̀ méjì jóná ráùráú níbi tí ọkọ̀ tó gbé bẹntiróò ti gbiná
Ijamba ọkọ agbepo to jona naa waye ni agbegbe Anthony lọ si Gbagada, ni ipinlẹ Eko.

Jimoh Aliu: Wo àwọn nkan tí o kò mọ̀ nípa Jimoh Aliu tó d'ólóògbé
Baba Jimoh Aliyu ti ọpọ mọ si Aworo jade laye lẹni ọgọrin ọdun, nile iwosan Fasiti Ado Ekiti.

Anambra Killing: Ojú oorun ni ìyá àtàwọn ọmọ méjèèjì wà nígbà tí ọkùnrin náà fi àdá pa wọ́n
Ileesẹ ọlọ́pàá tó fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ní ọkùnrin yìí tún ṣá ọmọ rẹ̀ mẹ́ta míì ní àdá, èyí tó fún wọn ní ọgbẹ́ ńlá.

Nigeria Airforce shortlist 2020: Iléeṣẹ́ ọmọogun òfúrufú kéde orúkọ àwọn tó yege ìdánwò àṣewọ'léeṣẹ́ ológun náà
Loju opo Twitter rẹ lo ti kede rẹ.

Oriire Oyo Farmers: Bí àwọn Darandaran ṣe ba okò opó kan jẹ́
Eyi ni iriri aburu awọn agbẹ odidi ijọba ibilẹ kan ni ipinlẹ Oyo pẹlu awọn darandaran ninu oko to jẹ ọna atijẹ wọn.

Precious Chikwendu àti Femi Fani-Kayode gba ayélujára kan lórí gbọ́yìsọ̀yì pé tírélà gba àárín wọn
Iroyin naa sọ pe ọpọ igba ni Fani Kayode ko iya fun iyawo rẹ nigba to wa ninu oyun awọn ẹta.

Self-certification form: Lẹ́yìn tí ìjọba Nàìjíríà pahùndà lóríi fọ́ọ̀mù tuntun, wo àwọn tọ́rọ̀ kàn
Ọjọ́bọ̀ ni ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gbé òfin tuntun jáde nípa àwọn tó ní àpò àsùnwọ̀n sí ilé ìfowópamọ́.

Sotitobire: Adájọ́ sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ìdájọ́ fún Wòlíì Sotitobire Alfa Babatunde
Osu keji ọdun yii ni Wòlíì Sotitobire Alfa Babatunde ti bẹrẹ si ni foju wina ẹjọ lori ẹsun ijọmọgbe.

Foluke Daramola: Òfin El-Rufai láti tẹ àfipábánilòpọ̀ ní ọ̀dá gbọ́dọ̀ di mímúṣẹ
Foluke Daramola, ti ayalegbe wọn fipa ba lopọ nigba to wa ni ọdọ, dunnu si ofin titẹ awọn afipabanilopọ ni ọda.

Manchester United vs Crystal Palace: Manchester United fi orí kó ògúlùtu ìyà olójú mẹ́ta sí ẹyọkan lọ́wọ́ Crystal Palace
Igba akọkọ niyi ti Crystal palace yoo maa bori ninu ifẹsẹ meji tẹlera ni ibẹrẹ saa liigi kan.

Fulham vs Arsenal: Arsenal lu Fulham ní àlùbami pẹ̀lú 3-0, ṣùgbọ́n ariwo Willian layé ń pa
Saa liigi tuntun Premiership bẹ̀rẹ̀ ni ilẹ Gẹẹsi lọjọ Abamẹta, Fulham ati Arsenal lo si ṣide rẹ.

Paul Sodje: Ọjọ́rùú ló yẹ kó pé ẹni ọdun 55, amọ́ tó kú ikú àìròtẹ́lẹ̀
Alaga Nigerian Scrabble Federation, Akintunde Akinsemola ni wọn ko tii ri aburo Paul Sodje, Chris ti wọn kọkọ jigbe.

Ifetedo FC: Ọ̀rẹ́ olóògbé ní Damilola kò sàìsàn, ó ń gbá bọ́ọ̀lu lọ́wọ́ ló kú
Ìròyìn sọ pé ni kété ti ọ̀rọ̀ náà ṣẹlẹ̀ ni wọ́n ti gbé ọmọkurin náà lọ si ilé ìwòsàn aládani kan fún ìtọ́jú.

Akomolede Yoruba: Ìtàn ọ̀rẹ́ tó fi ògùn gba ọkọ ọ̀rẹ́ rẹ̀ nílùú òyìnbó rèé
Arabinrin Olaitan Zainab ni olukọ to n ka itan ninu iwe ayọka Yoruba fun wa lonii.

African Eye: Ìwádìí BBC lórí ikú tó pa ọmọ ogun 26 ní Libya láti ipasẹ̀ Díróònù àìmọ̀dí
BBC Africa Eye ṣe àwárí rẹ̀ pé, ilẹ̀ United Arabi Emirate UAE ati Egypt lo n fi diroonu sere ọwọ lorilẹede Libya, eyi ti ko jẹ ki ogun sinmi nibẹ.

Ketu Flood: Ọ̀tọ̀ lọ̀rọ̀ táa ń pè ìjọba sí o, ẹ wá wò ó
Awọn olugbe Ketu nibi ti iroyin ni agbara ojo wọ ọmọ meji lọ ni ọtọ lohun tawọn n pe akiyesi ijọba si.

Adunni Oluwole: Akíkanjú obìnrin àkọ́kọ́ to dá ẹgbẹ́ òṣèlú àti tíátà silẹ ṣáájú Ogunde
Igbagbọ Adunni Oluwole, to fi tako ominira Naijiria ni pe awọn ọlaju yoo rẹ mẹkuunu jẹ lẹyin ominira, eyi to n waye bayii.

Penis Captivus: Nǹkan márùn-ún tí obìnrin àti ọkùnrin tó lẹ̀pọ̀ yóò ṣe láti yọ rèé
Dokita Ezenwakwo Francis ṣalaye fun BBC pe, isẹlẹ naa ko lọwọ aye ninu, kii si se Magun, gẹgẹ bi ẹya Yoruba ti maa n pe e.

Oba Olajide Olayode: Ó pe ọlọ́pàá láti yanjú aáwọ̀ ìlú lórí owó orí, bílísì bá dé
Ọgọọrọ ọlọpaa ati ologun ti wọn fi ransẹ silu Ogbomoso ko le dẹkun laasigbo naa, aimọye dukia bajẹ, ọpọ oku si sùn sinu isẹlẹ naa.

Mayowa Omoniyi: Olùkọ́ rẹ̀ ní òun ni atagìtá ''Hawaiian guitar'' tó kéré jùlọ lágbàáyé
BBC Yoruba ṣe alabapade Mayowa Omoniyi to dantọ pupọ ninu jita tita, eyi to jogun lara baba rẹ.

Osogbo JTF vs Youth Protest: Àwọn ẹbí Idris Ajibola ń fẹ́ ìdájọ́ lórí ikú ọmọ wọn
Inu ẹkun ati ọfọ ni mọlẹbi Idris Ajibola wa lọwọlọwọ.

Coronavirus Update: Ṣe ẹ mọ pe Covid-19 lee yọri si giri tabi ki eeyan daku rọngbọndan?
Ṣe ẹ mọ pe o lee bọ si ọpọlọ ti yoo si yọri si arun rọparọsẹ?

Ni Jigawa, àwọn obìnrin dáwó ra ọkọ̀ N1m láti máa fi gbé aláboyún ní iletò kan
Arabinrin Halima Adamu to lewaju igbesẹ naa ṣalaye fun BBC pe, wọn bẹrẹ pẹlu eto ẹdawo laarin ọkọọkan awọn obinrin ni ileto naa.

Bukunmi Oluwasina: Ìmọ̀ràn ọkọ mi nínú eré tí mo bá kọ lo ń jẹ́ kí eré mi dáńtọ́
Òwúrọ̀ Ọjọ́bọ ni Bukunmi Oluwasina kéde lójú òpó Instagram rẹ̀ pé òun ṣe ìgbéyàwó bòńkẹ́lẹ́.

Cuppydat: Ọmọdé aláwàdà Ikorodu Bois tún àwòrán Ferrari Portofino àwọn Otedola yà
Aworan tawọn ọmọ Otedola fi sita ti n mu iriwisi ọtọọtọ wa lọdọ awọn ọmọ Naijiria lori Twitter.

Lagos vs Ekiti Waste Baskets: Ìjọba Eko kọ́ ló rán àwọn ọ́ọ́físà tó ń ta apẹ̀rẹ̀ ikòlẹ̀sí níṣẹ́
Kọmiṣọnna ọrọ ayika ati alumọọni inu omi, Tunji Bello ṣalaye pe onijibi lawọn eeyan to n fipa ta apẹrẹ idalẹ si.

Osogbo JTF vs Youth Protest: Àwọn ẹbí Idris Ajibola bèrè fún ìwádìí tòótó lórí ikú ọmọ wọn
Iléese Ọlọ́pàá nipinle Osun sọ pé àwọn aráàlú kò jẹ́ kí àwọn dé ibi ìṣẹ̀lẹ̀ nàá.

Osun Osogbo Shrine Porn Video: Wo ìgbà méjì láàrín ọdún méjì tí ojúbọ Osun Osogbo ti mú ìròyìn àìtọ́ lọ́wọ́
Iroyin sọ pe ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ti tẹ King Tblak to ya fidio ibalopọ ninu igbo Osun Osogbo

Lesbian Movie Ife: Òṣèré méjì yìí ń fi ẹ̀wọ̀n runmú tóríi fíìmù "Ife" táwọn obìnrin ń bá ara wọn lòpọ̀
Wo ohun to wa ninu fiimu naa ti awọn ẹlẹsin Musulumi ṣe lodi si naa ti awọn onigbagbọ naa ko fara mọ ọ.

Gani Adams: Àwọn agbébọn ń jí ọmọdé, àwọn obìnrin, ti wọn sì ń dúnkookò mọ ọrọ̀ aje Oke Ogun
Fun igba keji laarin osu kan Aarẹ Ọna Kakanfo nilẹ Yoruba figbe bọnu nipa aifararọ eto aabo lagbegbe Oke Ogun.

Temitope Akinnusi: Ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ ló takú láti gbà mí síṣẹ́ torí mo ní ojú kan
Temitope Akinwusi, tii se ayaworan to ni oju kan ba BBC Yoruba sọrọ lori awọn idẹyẹsi ati ipenija to n koju nitori pe oju kan rẹ fọ.

Akomolede: Bolaji Faleke ni Olùkọ́ tó ń kọ́ wa ní àṣà oge ṣiṣe lórí BBC Yorùbá
Iwẹ wiwẹ, eyin pipa, irun gigẹ, osun kikun, ayika gbigba ati imọtoto paapaa lasiko Covid 19 yii wa lára ẹkọ ti a kọ lonii lori eto.

Amotekun: Toogun ní àwọn sá fún ariwo ni wọ́n ṣe ń ṣàyẹ̀wò fún ọ̀dọ́ 47,000 tó bèèrè iṣẹ́
Alaga ikọ Amotekun nipinlẹ Oyo ni awọn yoo finmu finlẹ lati mọ boya awọn eeyan yii ni akọsilẹ iwa ọdaran ri.

Alaafin: Olorì Folashade ní òun ni olorì àkọ́kọ́ tó bí ìbẹta nílẹ̀ Yorùbá
Ọkan lara awọn ayaba l'aafin Oyo, Olori Folashade Adeyemi sọ pe, ibanujẹ ni iroyin to jade nipa Olori Badrat ati KWAM 1 jẹ laafin Oyo.

Alaafin: Ọmọ ọdún 17 ní Ayaba Abibat Adeyemi nígbà tó fẹ́ ọkọ rẹ̀
Ọba Adeyemi ati Olori Abibat ko lee sọ ibi ti ori n ba ẹsẹ wọn re nigba ti wọn se igbeyawo sugbọn pẹlu ifẹ nla to wa laarin wọn, wọn gba pe ọla yoo dara.

Ondo Election 2020: Lóòtọ́ làwọn tọ́ọ̀gì APC kọlu PDP ní Oba Akoko, ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ - Ọ̀lọ́pàá
Ọpọ ọkọ lo bajẹ ninu ikọlu yii nigba ti ikọ ipolongo Eyitayo Jegede ati ti Rotimi Akeredolu pade ni Oba Akoko.

HUMILITASCharleans' Contribution Worldwide

300

Charlean Doctors

250

Charlean Engineers

150

Charlean Lawyers

109

Charlean Professors

We always perform at our best when we work together

Our mission is to provide the means & technical know-how to accomplish the aforementioned with HUMILITAS - always